Ìtúpalẹ̀ Ewì Aláwòrò-Ẹkùn Láàrin Àwọn Àwórì

Onírúurú ọdún ìbílẹ̀ ló wà láàrin Yorùbá, ọ̀ kan-ò-jọ̀ kan ìbọ ni wọ́ n sì máa ń fi sọrí àwọn ọdún ìbílẹ̀ wọ̀ nyí. Ó fẹ́ rẹ̀ ẹ́ má sí ìlú kan láwùjọ Yorùbá tí kò ní ọdún ìbílẹ̀ kan tí wọ́ n ń ṣe ní pàtó. Ọ̀rọ̀ nípa ìbọ àti ọdún ìbílẹ̀ kì í ṣe àjò...

Full description

Saved in:
Bibliographic Details
Main Author: Rifqat Ọpẹyẹmí Sanni ́
Format: Article
Language:English
Published: LibraryPress@UF 2021-12-01
Series:Yoruba Studies Review
Online Access:https://ojs.test.flvc.org/ysr/article/view/130102
Tags: Add Tag
No Tags, Be the first to tag this record!
Description
Summary:Onírúurú ọdún ìbílẹ̀ ló wà láàrin Yorùbá, ọ̀ kan-ò-jọ̀ kan ìbọ ni wọ́ n sì máa ń fi sọrí àwọn ọdún ìbílẹ̀ wọ̀ nyí. Ó fẹ́ rẹ̀ ẹ́ má sí ìlú kan láwùjọ Yorùbá tí kò ní ọdún ìbílẹ̀ kan tí wọ́ n ń ṣe ní pàtó. Ọ̀rọ̀ nípa ìbọ àti ọdún ìbílẹ̀ kì í ṣe àjòjì ní ìpínlẹ̀ Èkó, ní pàtàkì jù lọ láàrin àwọn Àwórì. Onírúurú iṣẹ́ akadá ni ó ti wà nílẹ̀ lórí ewì alohùn inú àwọn ọdún ìbílẹ̀ àti ìbọ ilẹ̀ Yorùba ṣùgbọ́ n kò sí èyíkéyìí nínú àwọn tí a ka tí ó gbájú mọ́ ìbọbìnrin láàrin àwọn Àwórì ní ìpínlẹ Èkó tàbí ewì inú ìbọ Aláwòrò-Ẹkùn tí iṣẹ́ yìí dá lé. Èyí mú kí á lè sọ pé, kò tí ì sí ìtúpalẹ̀ ewì ìbọbìnrin láàrin àwọn Àwórì ní ìpínlẹ Èkó tí a rí. Èròǹgbà wa nínú iṣẹ́ yìí ni láti ṣe ìtúpalẹ̀ ewì àti iṣẹ́ -ọnà inú ìbọ Aláwòrò- Ẹkùn láàrin àwọn Àwórì ní ìpínlẹ Èkó. A kò fi òdiwọn sí ewì alohun tí a múlò, a ṣe àgbàsílẹ̀ gbogbo èyí tí a bá pàdé nínú bíbọ Aláwòrò-Ẹkùn. A sì tún ṣe ìfọ̀ rọ̀ -wáni-lẹ́ nu-wò fún abọrẹ̀ Aláwòrò-Ẹkùn àti àwọn olùsìn mẹ́ ta. A ṣe ìtúpalẹ̀ àbọ̀ ìwádìí pẹ̀ lú tíọ́ rì ìfìwádìí-sọ̀ tumọ̀ àti tíọ́ rì jẹ́ ńdà. Èyí jẹ́ kí a ní òye pé, takọ-tabo ló ni ipa tí wọ́ n ń kó nínú ọdún àti bíbọ ìbọ Aláwòrò-Ẹkùn, bẹ́ ẹ̀ ni a rí ihà tí obìnrin kọ sí ọkùnrin, ìhà tí ọkùnrin kọ sí obìnrin, àti ìhà tí àwọn obìnrin kọ sí ara wọn ní ojúbọ. Ohun gbogbo tí a tọ́ ka sí nípa ewì alohùn Aláwòrò-Ẹkùn àti ìlò ohun èlò pọ̀ mọ́ ewì alohùn wọ̀ nyí jẹ́ kí a lè sọ pé ipa pàtàkì ni àwọn ewì alohùn ń kó nínú bíbọ ìbọ àti ọdún láwùjọ Yorùbá, àti ní pàtàkì jùlọ nínú ìbọ Aláwòrò-Ẹkùn láàrin àwọn Àwórì ní ìpínlẹ̀ Èkó.
ISSN:2473-4713
2578-692X