Ìlò Èébú Nínú Àwọn Ìtàn-àròsọ Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ Òkédìjí
Ògúnṣínà (1992), Adébọ̀wálé (1994) àti Ìṣọ̀lá (1995) ti ṣe àlàyé lórí ìlò èdè Òkédìjí nínú ìtàn-àròsọ Àjà Ló Lẹrù, Àgbàlagbà Akàn àti Ká Rìn Ká Pọ̀ ṣùgbọ́n kò sí lámèyítọ́ tó yẹ ìlò èébú wò nínú àwọn ìwé náà tàbí ti òǹkọ̀ wé ìtàn-àròsọ Yorùbá mìíràn. Iṣẹ́ yìí ṣe àyẹ̀ wò ìlò èébú nínú ìtàn-àròsọ Òk...
Saved in:
Main Authors: | , |
---|---|
Format: | Article |
Language: | English |
Published: |
LibraryPress@UF
2021-12-01
|
Series: | Yoruba Studies Review |
Online Access: | https://ojs.test.flvc.org/ysr/article/view/130088 |
Tags: |
Add Tag
No Tags, Be the first to tag this record!
|
Summary: | Ògúnṣínà (1992), Adébọ̀wálé (1994) àti Ìṣọ̀lá (1995) ti ṣe àlàyé lórí ìlò èdè Òkédìjí nínú ìtàn-àròsọ Àjà Ló Lẹrù, Àgbàlagbà Akàn àti Ká Rìn Ká Pọ̀ ṣùgbọ́n kò sí lámèyítọ́ tó yẹ ìlò èébú wò nínú àwọn ìwé náà tàbí ti òǹkọ̀ wé ìtàn-àròsọ Yorùbá mìíràn. Iṣẹ́ yìí ṣe àyẹ̀ wò ìlò èébú nínú ìtàn-àròsọ Òkédìjí, ó sì lo ọgbọ́ n ìwádìí kíka àwọn ìwé náà ní àkàtúnkà láti ṣe àfàyọ àti àkójọpọ̀ gbogbo èébú tó súyọ kí a tó ṣe ìtúpalẹ̀ wọn. Tíọ́rì ọ̀nà ìṣafọ̀ tó jẹmọ́ èròǹgbà aṣafọ̀ àti ìmọ̀lára òsùnsùn-afọ̀ nípa afọ̀ la fi ṣe àlàyé wa. Ìgbà ọ̀ọ́dúnrún àti ọ̀kandínláàádọ́rùn-ún ni Òkédìjí ti lo èébú nínú àwọn ìtàn-àròsọ rẹ̀, ọ̀nà ìṣafọ̀ méjì tó gbà ṣe àgbékalẹ̀ èébú ni ìṣafọ̀ sínú àti ìṣafọ̀ síta. Ìsọ̀ rí èébú wọ̀ nyí lè jẹ́ èébú ti ẹlẹ́ yọ-ọ̀ rọ̀ , alápòólà, odindi gbólóhùn, oníbéèrè, òwe àti oríkì ajẹméèébú. Iṣẹ́ tí àwọn aṣafọ̀ fi èébú ṣe nínú ìsọ̀ rọ̀ gbèsì la fi kásẹ̀ àlàyé wa.
|
---|---|
ISSN: | 2473-4713 2578-692X |